Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:22 - Bibeli Mimọ

22 Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:22
18 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo.


O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.


Natani si wi fun Dafidi pe, Iwọ li ọkunrin na. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Emi fi ọ jọba lori Israeli, emi si gbà ọ lọwọ Saulu;


Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun.


Nitori ti ãnu rẹ tobi jù ọrun lọ: ati otitọ rẹ titi de awọsanma.


Oluwa, ãnu rẹ de ọrun; otitọ rẹ de awọsanma.


Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.


Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ.


O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:


Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye.


Eyi ti ewe rẹ̀ lẹwà, ti eso rẹ̀ si pọ̀, ninu eyi ti onjẹ si wà fun gbogbo ẹda, labẹ eyi ti awọn ẹranko igbẹ ngbe, lori ẹka eyi ti awọn ẹiyẹ oju-ọrun ni ibugbe wọn.


Lẹhin oṣu mejila, o nrin kiri lori ãfin ijọba Babeli.


Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ.


Johanu sá ti wi fun u pe, ko tọ́ fun ọ lati ni i.


Nitori awọn ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gá ani de ọrun, Ọlọrun si ti ranti aiṣedẽdẽ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan