Daniẹli 4:16 - Bibeli Mimọ16 Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀. Faic an caibideilYoruba Bible16 kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní16 Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀. Faic an caibideil |
Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,