Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:14 - Bibeli Mimọ

14 O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:14
19 Iomraidhean Croise  

Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi.


Emi ti dá aiye, enia ati ẹranko ti o wà lori ilẹ aiye, nipa agbara nla mi, ati nipa ọwọ ninà mi, emi si fi i fun ẹnikẹni ti o wù mi.


Ẹ salọ kuro lãrin Babeli, ki olukuluku enia ki o si gbà ọkàn rẹ̀ là: ki a máṣe ke nyin kuro ninu aiṣedede rẹ̀; nitori eyi li àkoko igbẹsan fun Oluwa; yio san ère iṣẹ fun u.


Awa fẹ wò Babeli sàn, ṣugbọn kò sàn; ẹ kọ̀ ọ silẹ, ki ẹ si jẹ ki a lọ, olukuluku si ilẹ rẹ̀: nitori ẹbi rẹ̀ de ọrun, a si gbe e soke de awọsanma.


Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti on gbe ara rẹ̀ soke ni giga, o si ti yọ ṣonṣo rẹ̀ soke lãrin awọn ẹ̀ka didí, ọkàn rẹ̀ si gbe soke nitori giga rẹ̀;


O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:


Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo,


Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara.


Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,


Lẹhin oṣu mejila, o nrin kiri lori ãfin ijọba Babeli.


Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀:


A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀.


Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná.


Gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a ké e lùlẹ, a si wọ́ ọ sọ sinu iná.


Ati nisisiyi pẹlu, a fi ãke le gbòngbo igi na: gbogbo igi ti kò ba so eso rere, a ke e lulẹ, a si wọ́ ọ jù sinu iná.


O si ke li ohùn rara, bi igbati kiniun ba bú ramuramu: nigbati o si ké, awọn ãrá meje na fọhun.


O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan