Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:13 - Bibeli Mimọ

13 Mo ri ninu iran ori mi lori akete mi, si kiye si i, oluṣọ, ani ẹni mimọ́ kan sọkalẹ lati ọrun wá;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 “Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:13
18 Iomraidhean Croise  

On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si.


Ẹ fi ibukún fun Oluwa, ẹnyin angeli rẹ̀, ti o pọ̀ ni ipa ti nṣe ofin rẹ̀, ti nfi eti si ohùn ọ̀rọ rẹ̀.


Ọlọrun li o ni ìbẹru gidigidi ni ijọ enia mimọ́, o si ni ibuyìn-fun lati ọdọ gbogbo awọn ti o yi i ká.


Bayi ni iran ori mi lori akete mi; mo ri, si kiyesi i, igi kan duro li arin aiye, giga rẹ̀ si pọ̀ gidigidi.


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


Ati gẹgẹ bi ọba si ti ri oluṣọ́ kan ani ẹni mimọ́ ti o sọkalẹ lati ọrun wá, ti o si wipe, Ke igi na lulẹ, ki o si pa a run: ṣugbọn fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ lãye, ani ti on ti ìde irin ati ti idẹ, ninu koriko tutu igbẹ; ki a si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki ipin rẹ̀ si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ, titi ìgba meje yio fi kọja lori rẹ̀,


Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi.


LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na.


Awọn ẹranko nla wọnyi, ti o jẹ mẹrin, li awọn ọba mẹrin ti yio dide li aiye.


Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu.


Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?


Ẹnyin o si sá si afonifojì oke mi wọnni: nitoripe afonifoji oke na yio de Asali: nitõtọ, ẹnyin o sa bi ẹ ti sa fun ìṣẹ̀lẹ̀ nì li ọjọ Ussiah ọba Juda: Oluwa Ọlọrun mi yio si wá, ati gbogbo awọn Ẹni-mimọ́ pẹlu rẹ̀.


Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀:


O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun.


O ni, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ iṣe; Ẹni Mimọ́ Ọlọrun.


O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá.


Awọn wọnyi pẹlu ni Enoku, ẹni keje lati ọdọ Adamu, sọtẹlẹ fun, wipe Kiyesi i, Oluwa mbọ̀ pẹlu ẹgbẹgbãrun awọn enia rẹ̀ mimọ́,


On pẹlu yio mu ninu ọti-waini ibinu Ọlọrun, ti a tú jade li aini àbula sinu ago irunu rẹ̀; a o si fi iná ati sulfuru da a loró niwaju awọn angẹli mimọ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan