Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:12 - Bibeli Mimọ

12 Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:12
13 Iomraidhean Croise  

On a gbà aiya olú awọn enia aiye, a si ma mu wọn wọ́ kakiri ninu iju nibiti ọ̀na kò si.


Nitoripe abá wà fun igi, bi a ba ke e lulẹ, pe yio si tun sọ, ati pe ẹka rẹ̀ titun, kì yio dá.


Sibẹ nigbati o ba gbõrùn omi, yio sọ, yio si yọ ẹka jade bi eweko.


Ẽmi iho imu wa, ani ẹni-ororo Oluwa, ni a mu ninu ọ̀fin wọn, niti ẹniti awa wipe, labẹ ojiji rẹ̀ li awa o ma gbé lãrin awọn orilẹ-ède.


Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe.


Awọn pẹlu sọkalẹ lọ sinu ipò-okú pẹlu rẹ̀ sọdọ awọn ti a fi idà pa; awọn ti o si jẹ apá rẹ̀, ti ngbe abẹ òjiji rẹ̀ li ãrin awọn keferi.


O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:


Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀.


Ṣugbọn niti ọjọ ati wakati na, kò si ẹnikan ti o mọ̀ ọ, kò si, ki tilẹ iṣe awọn angẹli ọrun, tabi Ọmọ, bikoṣe Baba mi nikanṣoṣo.


Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀.


O dabi wóro irugbin mustardi, ti ọkunrin kan mú, ti o si sọ sinu ọgbà rẹ̀; ti o si hù, o si di igi nla; awọn ẹiyẹ oju ọrun si ngbé ori ẹká rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan