Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:11 - Bibeli Mimọ

11 Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:11
6 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wipe, Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a tẹ̀ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyiti yio si kàn ọrun; ki a si li orukọ, ki a má ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo.


Ati awọn alejo, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ède, ti ké e kuro, nwọn si ti tú u ká; ẹka rẹ̀ ṣubu sori awọn oke, ati ninu gbogbo afonifoji, ẹka rẹ̀ si ṣẹ́ lẹba gbogbo odò ilẹ na; gbogbo awọn orilẹ-ède aiye si jade lọ kuro labẹ òjiji rẹ̀, nwọn si fi i silẹ.


Nitorina a gbe giga rẹ̀ soke jù gbogbo igi igbẹ́ lọ, ẹ̀ka rẹ̀ si di pupọ̀, awọn ẹ̀ka rẹ̀ si di gigùn nitori ọ̀pọlọpọ omi, nigbati o yọ wọn jade.


Ati iwọ Kapernaumu, a o ha gbé ọ ga soke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ si Ipo-oku: nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu rẹ ninu Sodomu, on iba wà titi di oni.


GBỌ́, Israeli: iwọ o gòke Jordani li oni, lati wọle lọ ìgba awọn orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù ọ lọ, ilu ti o tobi, ti a mọdi rẹ̀ kàn ọrun,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan