Daniẹli 4:1 - Bibeli Mimọ1 NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. Faic an caibideilYoruba Bible1 Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nebukadnessari ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé: Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Faic an caibideil |
Nigbana li a pè awọn akọwe ọba ni ọjọ kẹtala, oṣù kini, a si kọwe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti Hamani ti pa li aṣẹ fun awọn bãlẹ ọba, ati fun awọn onidajọ ti o njẹ olori gbogbo ìgberiko, ati fun awọn olori olukuluku enia ìgberiko gbogbo, gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati fun olukuluku enià gẹgẹ bi ède rẹ̀, li orukọ Ahaswerusi ọba li a kọ ọ, a si fi oruka ọba ṣe edidi rẹ̀.
Nigbana li a si pè awọn akọwe ọba li akokò na ni oṣù kẹta, eyini ni oṣù Sifani, li ọjọ kẹtalelogun rẹ̀; a si kọ ọ gẹgẹ bi Mordekai ti paṣẹ si awọn Ju, ati si awọn bãlẹ, ati awọn onidajọ, ati olori awọn ìgberiko metadilãdoje, si olukulùku ìgberiko gẹgẹ bi ikọwe rẹ̀, ati si olukulùku enia gẹgẹ bi ède wọn ati si awọn Ju gẹgẹ bi ikọwe wọn, ati gẹgẹ bi ède wọn.