Daniẹli 3:6 - Bibeli Mimọ6 Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo. Faic an caibideilYoruba Bible6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.” Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.” Faic an caibideil |
Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi.