Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:3 - Bibeli Mimọ

3 Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nítorí náà, gbogbo wọn wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère náà, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:3
11 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Nebukadnessari ọba, ranṣẹ lọ ipè awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, ati awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko, lati wá si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari ọba, gbé kalẹ.


Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn.


Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo,


Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.


Awọn wọnyi ni inu kan, nwọn o si fi agbara ati ọla wọn fun ẹranko na.


Nitori Ọlọrun ti fi sinu ọkàn wọn lati mu ifẹ rẹ̀ ṣẹ, lati ni inu kan, ati lati fi ijọba wọn fun ẹranko na, titi ọ̀rọ Ọlọrun yio fi ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan