Daniẹli 3:25 - Bibeli Mimọ25 O si dahùn wipe, Wò o, mo ri ọkunrin mẹrin ni titu, nwọn sì nrin lãrin iná, nwọn kò si farapa, ìrisi ẹnikẹrin si dabi ti Ọmọ Ọlọrun. Faic an caibideilYoruba Bible25 Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.” Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní25 Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.” Faic an caibideil |
Nigbana ni Nebukadnessari dahùn o si wipe, Olubukún li Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ẹniti o rán angeli rẹ̀ ti o si gbà awọn iranṣẹ rẹ̀ la, ti o gbẹkẹ le e, nwọn si pa ọ̀rọ ọba da, nwọn si fi ara wọn jìn, ki nwọn ki o má ṣe sìn, tabi ki nwọn ki o tẹriba fun oriṣakoriṣa bikoṣe Ọlọrun ti awọn tikarawọn.