Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:23 - Bibeli Mimọ

23 Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:23
13 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pọlọpọ ni ipọnju olododo; ṣugbọn Oluwa gbà a ninu wọn gbogbo.


Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.


Nwọn si mu Jeremiah, nwọn si sọ ọ sinu iho Malkiah ọmọ Hammeleki, ti o wà li agbala ile-túbu: nwọn fi okun sọ Jeremiah kalẹ sisalẹ. Omi kò si si ninu iho na, bikoṣe ẹrẹ̀: Jeremiah si rì sinu ẹrẹ̀ na.


Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego.


Nigbana ni Nebukadnessari ọba warìri o si dide duro lọgan, o dahùn, o si wi fun awọn ìgbimọ rẹ̀ pe, awọn ọkunrin mẹta kọ a gbé sọ si ãrin iná ni didè? Nwọn si dahùn wi fun ọba pe, Lõtọ ni ọba.


Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.


Ti nwọn pa agbara iná, ti nwọn bọ́ lọwọ oju-idà, ti a sọ di alagbara ninu ailera, ti nwọn di akọni ni ìja, nwọn lé ogun awọn àjeji sá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan