Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:2 - Bibeli Mimọ

2 Nigbana ni Nebukadnessari ọba, ranṣẹ lọ ipè awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, ati awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko, lati wá si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari ọba, gbé kalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:2
10 Iomraidhean Croise  

Jeroboamu si dá àse silẹ li oṣu kẹjọ, li ọjọ kẹdogun oṣu, gẹgẹ bi àse ti o wà ni Juda, o si gun ori pẹpẹ na lọ: bẹ̃ni o si ṣe ni Beteli, o rubọ si awọn ọmọ-malu ti o ṣe: o si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti o ti ṣe si Beteli.


Bi ijoye ba feti si ọ̀rọ-eke, gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ni yio buru.


Nigbana ni awọn ọmọ-alade, bãlẹ, balogun, ati awọn ìgbimọ ọba ti o pejọ ri pe iná kò lagbara lara awọn ọkunrin wọnyi, bẹ̃ni irun ori wọn kan kò jona, bẹ̃li aṣọ wọn kò si pada, õrùn iná kò tilẹ kọja lara wọn.


Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.


Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn.


Ẹniti awọn ọba aiye ba ṣe àgbere, ti a si ti fi ọti-waini àgbere rẹ̀ pa awọn ti ngbe inu aiye.


Nigbana ni awọn ijoye Filistini kó ara wọn jọ lati ru ẹbọ nla kan si Dagoni oriṣa wọn, ati lati yọ̀: nitoriti nwọn wipe, Oriṣa wa fi Samsoni ọtá wa lé wa lọwọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan