Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:19 - Bibeli Mimọ

19 Nigbana ni Nebukadnessari kún fun ibinu, àwọ oju rẹ̀ si yipada si Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego: o dahùn, o si paṣẹ pe, ki nwọn ki o da iná ileru na ki õru rẹ̀ gboná niwọn igba meje jù bi a ti imu u gboná ri lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

19 Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:19
26 Iomraidhean Croise  

Jakobu si wò oju Labani, si kiyesi i, kò ri si i bi ìgba atijọ.


Nigbati Hamani si ri pe, Mordekai kò kunlẹ, bẹ̃ni kò wolẹ fun on, nigbana ni Hamani kún fun ibinu.


Ọba si dide ni ibinu rẹ̀ kuro ni ibi àse ti nwọn nmu ọti-waini, o bọ́ si àgbala ãfin. Hamani si dide duro lati tọrọ ẹmi rẹ̀ lọwọ Esteri ayaba; nitori o ti ri pe ọba ti pinnu ibi si on.


Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.


Ibinu ọba dabi iranṣẹ ikú: ṣugbọn ọlọgbọ́n enia ni yio tù u.


Agberaga ati agidi ẹlẹgàn li orukọ rẹ̀, ẹniti nhùwa ninu ibinu pupọpupọ.


Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.


Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run.


Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba.


O si paṣẹ fun awọn ọkunrin ani awọn alagbara julọ ninu ogun rẹ̀ pe ki nwọn ki o di Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ki nwọn ki o si sọ wọn sinu iná ileru na ti njo.


Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.


Ọba si paṣẹ, pe ki a mu awọn ọkunrin wọnni wá, ti o fi Danieli sùn, nwọn si gbé wọn sọ sinu iho kiniun, awọn, ati awọn ọmọ wọn, ati awọn aya wọn. Ki nwọn ki o to de isalẹ iho, awọn kiniun bori wọn, nwọn si fọ egungun wọn tũtu.


Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin.


Bi ẹnyin ba si nrìn lodi si mi, ti ẹnyin kò si gbọ́ ti emi; emi o si mú iyọnu ìgba meje wá si i lori nyin gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ nyin.


Nigbana li emi pẹlu yio ma rìn lodi si nyin, emi o si jẹ nyin ni ìya si i ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.


Nigbana li emi o ma rìn lodi si nyin pẹlu ni ikannu; emi pẹlu yio si nà nyin ni ìgba meje nitori ẹ̀ṣẹ nyin.


Ṣugbọn nigbati nwọn gbọ́ eyi, àiya wọn gbà ọgbẹ́ de inu, nwọn gbèro ati pa wọn.


Nigbati nwọn si gbọ́ nkan wọnyi, àiya wọn gbọgbẹ́ de inu, nwọn si pahin si i keke.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan