Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:14 - Bibeli Mimọ

14 Nebukadnessari dahùn, o si wi fun wọn pe, otitọ ha ni, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, pe, ẹnyin kò sìn oriṣa mi, ẹ kò si tẹriba fun ere wura na ti mo gbé kalẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

14 Ó bi wọ́n léèrè pé, “Ṣé nítòótọ́ ni ẹ kò fi orí balẹ̀, kí ẹ sì sin ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:14
5 Iomraidhean Croise  

BELI tẹriba, Nebo bẹrẹ̀, oriṣa wọn wà lẹhin awọn ẹranko, ati lẹhin ohun-ọ̀sin; a di ẹrù wiwo rù nyin; ẹrù fun awọn ẹranko ti ãrẹ̀ mu.


Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu.


NEBUKADNESSARI ọba, si yá ere wura kan, eyi ti giga rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa: o si gbé e kalẹ ni pẹtẹlẹ Dura, ni igberiko Babeli.


Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan