Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:5 - Bibeli Mimọ

5 Ọba dahùn o si wi fun awọn Kaldea pe, ohun na ti kuro li ori mi: bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi ati itumọ̀ rẹ̀ pẹlu, a o ké nyin wẹwẹ, a o si sọ ile nyin di ãtàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi: tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:5
10 Iomraidhean Croise  

Nwọn si wo ere Baali lulẹ, nwọn si wo ile Baali lulẹ, nwọn si ṣe e ni ile igbẹ́ titi di oni yi.


Pẹlupẹlu mo ti paṣẹ pe, ẹnikẹni ti o ba yi ọ̀rọ yi pada, ki a fa igi lulẹ li ara ile rẹ̀, ki a si gbe e duro, ki a fi on na kọ si ori rẹ̀, ki a si sọ ile rẹ̀ di ãtàn nitori eyi.


Njẹ rò eyi, ẹnyin ti o gbagbe Ọlọrun, ki emi ki o má ba fà nyin ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ti kò si olugbala.


Ki nwọn ki o yọ́ danu bi omi ti nṣàn nigbagbogbo: nigbati o ba fa ọrun lati tafà rẹ̀, ki nwọn ki o dabi ẹnipe a ke wọn ni ijanja.


Nitori ọ̀ran yi ni inu ọba fi bajẹ, o si binu gidigidi, o si paṣẹ pe ki nwọn ki o pa gbogbo awọn amoye Babeli run.


Nitorina, emi paṣẹ pe, olukulùku enia, orilẹ, ati ède, ti o ba sọ ọ̀rọ odi si Ọlọrun Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, a o ke e wẹwẹ, a o si sọ ile rẹ̀ di àtan: nitori kò si Ọlọrun miran ti o le gbà ni là bi iru eyi.


Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀.


Ki iwọ ki o si kó gbogbo ikogun rẹ̀ si ãrin igboro rẹ̀, ki iwọ ki o si fi iná kun ilu na, ati gbogbo ikogun rẹ̀ patapata fun OLUWA Ọlọrun rẹ: ki o si ma jasi òkiti lailai; a ki yio si tun tẹ̀ ẹ dó mọ́.


Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró.


Samueli si wipe, Gẹgẹ bi idà rẹ ti sọ awọn obinrin di alaili ọmọ, bẹ̃ gẹgẹ ni iya rẹ yio si di alaili ọmọ larin obinrin. Samueli si pa Agagi niwaju Oluwa ni Gilgali.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan