Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:26 - Bibeli Mimọ

26 Ọba dahùn o si wi fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari pe, Iwọ le fi alá ti mo la hàn fun mi, ati itumọ rẹ̀ pẹlu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

26 Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

26 Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:26
9 Iomraidhean Croise  

Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego.


Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba.


Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn.


Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe,


Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò le tọ Filistini yi lọ lati ba a jà: nitoripe ọdọmọde ni iwọ, on si jẹ jagunjagun lati igba ewe rẹ̀ wá.


Farao sí wi fun Josefu pe, Emi lá alá, kò si si ẹnikan ti o le tumọ̀ rẹ̀: emi si gburó rẹ pe, bi iwọ ba gbọ́ alá, iwọ le tumọ̀ rẹ̀.


LI ọdun kini Belṣassari, ọba Babeli, ni Danieli lá alá, ati iran ori rẹ̀ lori akete rẹ̀: nigbana ni o kọwe alá na, o si sọ gbogbo ọ̀rọ na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan