Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:23 - Bibeli Mimọ

23 Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

23 Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi, ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún, nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára, o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí, nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi: ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:23
33 Iomraidhean Croise  

OLUWA si wipe, Emi o ha pa ohun ti emi o ṣe mọ́ fun Abrahamu:


Bikoṣe bi Ọlọrun baba mi, Ọlọrun Abrahamu, ati ẹ̀ru Isaaki ti wà pẹlu mi, nitõtọ ofo ni iwọ iba rán mi jade lọ. Ọlọrun ri ipọnju mi, ati lãla ọwọ́ mi, o si ba ọ wi li oru aná.


O si ṣe, ni irubọ aṣalẹ, ni Elijah woli sunmọ tòsi, o si wipe, Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, jẹ ki o di mimọ̀ loni pe, iwọ li Ọlọrun ni Israeli, emi si ni iranṣẹ rẹ, ati pe mo ṣe gbogbo nkan wọnyi nipa ọ̀rọ rẹ.


Oluwa Ọlọrun wa ki o wà pẹlu wa, bi o ti wà pẹlu awọn baba wa: ki o má fi wa silẹ, ki o má si ṣe kọ̀ wa silẹ;


Nitorina Dafidi fi iyìn fun Oluwa li oju gbogbo ijọ: Dafidi si wipe, Olubukún ni Iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli baba wa lai ati lailai!


Njẹ nisisiyi, Ọlọrun wa, awa dupẹ lọwọ rẹ, a si yìn orukọ ogo rẹ.


O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju?


Iwọ ti fi ifẹ ọkàn rẹ̀ fun u, iwọ kò si dù u ni ibère ẹnu rẹ̀.


O tọrọ ẹmi lọwọ rẹ, iwọ si fi fun u, ani ọjọ gigùn lai ati lailai.


Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀.


Ru ẹbọ-ọpẹ si Ọlọrun, ki o si san ẹjẹ́ rẹ fun Ọga-ogo.


Ọlọrun si wi fun Mose pẹlu pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn ọmọ Israeli; OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o rán mi si nyin: eyi li orukọ mi titilai, eyi si ni iranti mi lati irandiran.


Ọlọgbọ́n gùn odi ilu awọn alagbara, a si fi idi agbara igbẹkẹle rẹ̀ jalẹ̀.


Ọlọgbọ́n enia li agbara: nitõtọ enia ìmọ a sọ agbara rẹ̀ di pupọ.


Temi ni ìmọ ati ọgbọ́n ti o yè: emi li oye, emi li agbara.


Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu.


Nigbana ni mo wipe, Ọgbọ́n san jù agbara lọ; ṣugbọn a kẹgan ọgbọ́n ọkunrin talaka na, ohùn rẹ̀ kò si to òke.


Ọgbọ́n san jù ohun-elo ogun: ṣugbọn ẹ̀lẹṣẹ kan o ba ohun didara pupọ jẹ.


ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu.


Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.


Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá.


Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli.


Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀.


Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́.


Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ.


Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi.


Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin.


IFIHÀN ti Jesu Kristi, ti Ọlọrun fifun u, lati fihàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀ ohun ti kò le ṣaiṣẹ ni lọ̃lọ; o si ranṣẹ o si fi i hàn lati ọwọ́ angẹli rẹ̀ wá fun Johanu, iranṣẹ rẹ̀:


Ọkan ninu awọn àgba na si wi fun mi pe, Máṣe sọkun: kiyesi i, Kiniun ẹ̀ya Juda, Gbòngbo Dafidi, ti bori lati ṣí iwe na, ati lati tú èdidi rẹ̀ mejẽje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan