Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:22 - Bibeli Mimọ

22 O fi ohun ijinlẹ ati aṣiri hàn: o mọ̀ ohun ti o wà li òkunkun, lọdọ rẹ̀ ni imọlẹ si wà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn; ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn, ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn; ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:22
37 Iomraidhean Croise  

Josefu si da Farao li ohùn pe, Ki iṣe emi: Ọlọrun ni yio fi idahùn alafia fun Farao.


O hudi ohun ti o sigbẹ jade lati inu òkunkun wá, o si mu ojiji ikú jade wá sinu imọlẹ̀.


Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.


Ẹniti o fi imọlẹ bora bi aṣọ: ẹniti o ta ọrun bi aṣọ tita:


Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀.


Nitori pe pẹlu rẹ li orisun ìye wà: ninu imọlẹ rẹ li awa o ma ri imọlẹ.


TALI o dabi ọlọgbọ́n enia? tali o si mọ̀ itumọ nkan? Ọgbọ́n enia mu oju rẹ̀ dán, ati igboju rẹ̀ li a o si yipada.


Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa.


Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin.


Kiyesi i, nkan iṣãju ṣẹ, nkan titun ni emi si nsọ: ki nwọn to hù, mo mu nyin gbọ́ wọn.


Mo dá imọlẹ, mo si dá okunkun: mo ṣe alafia, mo si dá ibi: Emi Oluwa li o ṣe gbogbo wọnyi.


Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?


Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.


Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara.


Nigbana ni a fi aṣiri na hàn fun Danieli ni iran li oru, Danieli si fi ibukún fun Ọlọrun, Oluwa ọrun.


Ọba da Danieli lohùn, o si wipe, Lõtọ ni, pe Ọlọrun nyin li Ọlọrun awọn ọlọrun ati Oluwa awọn ọba, ati olufihàn gbogbo aṣiri, nitori ti iwọ le fi aṣiri yi hàn.


Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ:


Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ,


Nitorina ni mo ṣe nfi owe ba wọn sọ̀rọ; nitori ni riri, nwọn kò ri, ati ni gbigbọ, nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni kò yé wọn.


Imọlẹ otitọ mbẹ ti ntàn mọlẹ fun olúkulùku enia ti o wá si aiye.


O wi fun u nigba kẹta pe, Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹràn mi bi? Inu Peteru bajẹ, nitoriti o wi fun u nigba ẹkẹta pe, Iwọ fẹràn mi bi? O si wi fun u pe, Oluwa, iwọ mọ̀ ohun gbogbo; iwọ mọ̀ pe, mo fẹràn rẹ. Jesu wi fun u pe, Mã bọ́ awọn agutan mi.


Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.


Nitorina, ẹ máṣe ṣe idajọ ohunkohun ṣaju akokò na, titi Oluwa yio fi de, ẹniti yio mu ohun òkunkun ti o farasin wá si imọlẹ, ti yio si fi ìmọ ọkàn hàn: nigbana li olukuluku yio si ni iyìn tirẹ̀ lọdọ Ọlọrun.


Eyiti a kò ti fihàn awọn ọmọ enia rí ni irandiran miran, bi a ti fi wọn hàn nisisiyi fun awọn aposteli rẹ̀ mimọ́ ati awọn woli nipa Ẹmí;


OLUWA si fà wọn tu kuro ni ilẹ wọn ni ibinu, ati ni ikannu, ati ni irunu nla, o si lé wọn lọ si ilẹ miran, bi o ti ri li oni yi.


Ẹnikanṣoṣo ti o ni aikú, ti ngbe inu imọlẹ ti a kò le sunmọ, ẹniti enia kan kò ri rí ti kò si le ri: ẹniti ọla ati agbara titi lai iṣe tirẹ. Amin.


Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.


Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.


Eyi si ni iṣẹ ti awa ti gbọ́ lẹnu rẹ̀ ti awa si njẹ́ fun nyin, pe imọlẹ li Ọlọrun, òkunkun kò si sí lọdọ rẹ̀ rara.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan