Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:21 - Bibeli Mimọ

21 O si nyi ìgba ati akokò pada: o nmu ọba kuro, o si ngbe ọba leke: o si nfi ọgbọ́n fun awọn ọlọgbọ́n, ati ìmọ fun awọn ti o mọ̀ oye:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà; ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò. Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:21
40 Iomraidhean Croise  

Gbogbo aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀, ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.


Gbogbo Israeli si gbọ́ idajọ ti ọba ṣe; nwọn si bẹ̀ru niwaju ọba: nitoriti nwọn ri i pe, ọgbọ́n Ọlọrun wà ninu rẹ̀, lati ṣe idajọ.


Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.


Kiki ki Oluwa ki o fun ọ li ọgbọ́n ati oye, ki o si fun ọ li aṣẹ niti Israeli, ki iwọ ki o le pa ofin Oluwa Ọlọrun rẹ mọ́.


Pẹlu gbogbo jijọba ati ipá rẹ̀, ati ìgba ti o kọja lori rẹ̀, ati lori Israeli, ati lori gbogbo ijọba ilẹ wọnni.


Ọba si bi awọn ọlọgbọ́n, ti nwọn moye akokò, (nitori bẹ̃ni ìwa ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ:


O tu ide ọba, o si fi àmure gbà wọn li ọ̀ja.


Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà.


Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:


Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá.


LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na.


Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.


Danieli dahùn o si wipe, Olubukún ni orukọ Ọlọrun titi lai; nitori tirẹ̀ li ọgbọ́n ati agbara.


Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.


Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba fi alá na hàn fun mi, njẹ ipinnu kan li ẹnyin ti ṣe: nitoriti ẹnyin mura lati ma sọ̀rọ eke ati idibajẹ niwaju mi, titi akoko yio fi kọja: nitorina ẹ rọ́ alá na fun mi emi o si mọ̀ pe ẹnyin o le fi itumọ̀ rẹ̀ hàn fun mi pẹlu.


O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀:


Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.


Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.


A o si le ọ kuro larin enia, ibugbe rẹ yio si wà pẹlu awọn ẹranko igbẹ: nwọn o si mu ọ jẹ koriko bi malu, igba meje yio si kọja lori rẹ, titi iwọ o fi mọ̀ pe, Ọga-ogo ni iṣe olori ninu ijọba enia, on a si fi i fun ẹnikẹni ti o wù u.


On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò.


Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju.


KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá.


Ṣugbọn nipasẹ rẹ̀ li ẹnyin wà ninu Kristi Jesu, ẹniti Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n, ati ododo, ati isọdimimọ́, ati idande fun wa:


Gbogbo ẹ̀bun rere ati gbogbo ẹ̀bun pipé lati oke li o ti wá, o si nsọkalẹ lati ọdọ Baba imọlẹ wá, lọdọ Ẹniti kò le si iyipada tabi ojiji àyida.


Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia ni ọ̀pọlọpọ, ti kì isi ibaniwi; a o si fifun u.


O si ni lara aṣọ rẹ̀ ati ni itan rẹ̀ orukọ kan ti a kọ: ỌBA AWỌN ỌBA, ATI OLUWA AWỌN OLUWA.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan