Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:18 - Bibeli Mimọ

18 Pe, ki nwọn ki o bère ãnu lọwọ Ọlọrun, Oluwa ọrun, nitori aṣiri yi: ki Danieli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ má ba ṣegbe pẹlu awọn ọlọgbọ́n Babeli iyokù, ti o wà ni Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

18 pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:18
22 Iomraidhean Croise  

Bọya marun a dín ninu ãdọta olododo na: iwọ o ha run gbogbo ilu na nitori marun? On si wipe, Bi mo ba ri marunlelogoji nibẹ̀, emi ki yio run u.


Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.


Ki o si kepè mi ni ọjọ ipọnju: emi o gbà ọ, iwọ o si ma yìn mi logo.


On o pè orukọ mi, emi o si da a lohùn: emi o pẹlu rẹ̀ ninu ipọnju, emi o gbà a, emi o si bu ọlá fun u.


Bọya Oluwa Ọlọrun rẹ yio gbọ́ ọ̀rọ Rabṣake, ẹniti oluwa rẹ̀ ọba Assiria ti rán lati gàn Ọlọrun alãyè, yio si ba ọ̀rọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ ti gbọ́ wi: nitorina gbe adura rẹ soke fun awọn iyokù ti o kù.


Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli yio bere eyi lọwọ mi, lati ṣe e fun wọn, emi o mu enia bi si i fun wọn bi ọwọ́-ẹran.


Mo dupẹ lọwọ rẹ, mo si fi iyìn fun ọ, iwọ Ọlọrun awọn baba mi, ẹniti o fi ọgbọ́n ati agbara fun mi, ti o si fi ohun ti awa bère lọwọ rẹ hàn fun mi nisisiyi: nitoriti iwọ fi ọ̀ran ọba hàn fun wa nisisiyi.


Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba.


Ati gẹgẹ bi nwọn si ti paṣẹ pe ki nwọn ki o fi kukute gbòngbo igi na silẹ, ijọba rẹ yio jẹ tirẹ, lẹhin igbati o ba ti mọ̀ pe, ọrun ni iṣe olori.


On si wi fun wọn pe, Heberu li emi; mo si bẹ̀ru Oluwa, Ọlọrun ọrun, ti o dá okun ati iyangbẹ ilẹ.


Nigbana li ẹnyin o yipada, ẹ o si mọ̀ iyatọ̀ lãrin olododo ati ẹni-buburu, lãrin ẹniti nsìn Ọlọrun, ati ẹniti kò sìn i.


Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?


Mo wi fun nyin ẹ̀wẹ pe, Bi ẹni meji ninu nyin ba fi ohùn ṣọkan li aiye yi niti ohunkohun ti nwọn o bère; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti mbẹ li ọrun wá.


Nigbati o si mu u, o fi i sinu tubu, o fi i le ẹ̀ṣọ́ mẹrin awọn ọmọ-ogun lọwọ lati ma ṣọ ọ; o nrò lati mu u jade fun awọn enia wá lẹhin Irekọja.


Mo si bẹ̀ nyin, ará, nitori Oluwa wa Jesu Kristi, ati nitori ifẹ Ẹmí, ki ẹnyin ki o ba mi lakaka ninu adura nyin si Ọlọrun fun mi;


Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ:


Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan