Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 2:11 - Bibeli Mimọ

11 Ohun ti o tilẹ ṣọwọ́n ni ọba bère, kò si si ẹlomiran ti o le fi i hàn niwaju ọba bikoṣe awọn oriṣa, ibugbe ẹniti kì iṣe ninu ẹran-ara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 2:11
25 Iomraidhean Croise  

Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ:


O si ṣe li owurọ̀, ti ọkàn rẹ̀ kò lelẹ; o si ranṣẹ o si pè gbogbo awọn amoye Egipti, ati gbogbo awọn ọ̀mọran ibẹ̀ wá: Farao si rọ́ alá rẹ̀ fun wọn: ṣugbọn kò sí ẹnikan ti o le tumọ wọn fun Farao.


Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́?


Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́!


Eyi ni ibi isimi mi lailai: nihin li emi o ma gbe; nitori ti mo fẹ ẹ.


Iwọ ti gòke si ibi giga, iwọ ti di igbekun ni igbekun lọ: iwọ ti gbà ẹ̀bun fun enia: nitõtọ, fun awọn ọlọtẹ̀ pẹlu, ki Oluwa Ọlọrun ki o le ma ba wọn gbe.


Emi o si ma gbé ãrin awọn ọmọ Israeli, emi o si ma ṣe Ọlọrun wọn.


Nigbana ni awọn alalupayida wi fun Farao pe, Ika Ọlọrun li eyi: ṣugbọn àiya Farao le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.


Duro nisisiyi, ti iwọ ti iṣẹ afọṣẹ rẹ, ati ọpọlọpọ iṣẹ ajẹ́ rẹ, eyi ti o ti fi nṣe iṣẹ iṣe lati igba ewe rẹ wá; bi o ba ṣepe o lè jẹ erè fun ọ, bi o ba ṣe pe iwọ lè bori.


Nitori bayi li Ẹni-giga, ati ẹniti a gbéga soke sọ, ti ngbe aiyeraiye, orukọ ẹniti ijẹ Mimọ́, emi ngbe ibi giga ati mimọ́, ati inu ẹniti o li ẹmi irobinujẹ on irẹlẹ pẹlu, lati mu ẹmi awọn onirẹlẹ sọji, ati lati mu ọkàn awọn oniròbinujẹ sọji.


Kiyesi i, emi ati awọn ọmọ ti Oluwa ti fi fun mi wà fun àmi ati fun iyanu ni Israeli, lati ọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti ngbe òke Sioni.


Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi:


Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ:


Nitori emi o wẹ̀ ẹjẹ̀ wọn nù, ti emi kò ti wẹ̀nu: nitori Oluwa ngbe Sioni.


Iwọ kò si gbọdọ sọ ilẹ na di alaimọ́, ninu eyiti ẹnyin o joko, ninu eyiti emi ngbé: nitori Emi JEHOFA ni ngbé inu awọn ọmọ Israeli.


Ṣugbọn Jesu wò wọn, o si wi fun wọn pe, Enia li eyi ṣoro fun; ṣugbọn fun Ọlọrun ohun gbogbo ni ṣiṣe.


Ọ̀rọ na si di ara, on si mba wa gbé, (awa si nwò ogo rẹ̀, ogo bi ti ọmọ bíbi kanṣoṣo lati ọdọ Baba wá,) o kún fun ore-ọfẹ ati otitọ.


Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin.


Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀.


Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.


Mo si gbọ́ ohùn nla kan lati ori itẹ́ nì wá, nwipe, Kiyesi i, agọ́ Ọlọrun wà pẹlu awọn enia, on ó si mã ba wọn gbé, nwọn o si mã jẹ enia rẹ̀, ati Ọlọrun tikararẹ̀ yio wà pẹlu wọn, yio si mã jẹ Ọlọrun wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan