Daniẹli 2:10 - Bibeli Mimọ10 Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri. Faic an caibideilYoruba Bible10 Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní10 Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀. Faic an caibideil |