Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:8 - Bibeli Mimọ

8 Emi si gbọ́, ṣugbọn kò ye mi: nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini yio ṣe ikẹhin wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:8
9 Iomraidhean Croise  

Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe.


Ẹnikan si wi fun ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla ti o duro lori omi odò pe, opin ohun iyanu wọnyi yio ti pẹ to?


Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari.


O si wipe, Ma ba ọ̀na rẹ lọ, Danieli, nitoriti a ti se ọ̀rọ na mọ sọhún, a si fi edidi di i titi fi di igba ikẹhin.


Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?


Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.


Nkan wọnyi kò tète yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ṣugbọn nigbati a ṣe Jesu logo, nigbana ni nwọn ranti pe, a kọwe nkan wọnyi niti rẹ̀, ati pe, on ni nwọn ṣe nkan wọnyi si.


O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀.


Nwọn nwadi igba wo tabi irú sã wo ni Ẹmi Kristi ti o wà ninu wọn ntọ́ka si, nigbati o jẹri ìya Kristi tẹlẹ ati ogo ti yio tẹlé e.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan