Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:6 - Bibeli Mimọ

6 Ẹnikan si wi fun ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla ti o duro lori omi odò pe, opin ohun iyanu wọnyi yio ti pẹ to?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:6
16 Iomraidhean Croise  

Awa kò ri àmi wa: kò si woli kan mọ́: bẹ̃ni kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi yio ti pẹ to.


Si kiyesi i, ọkunrin mẹfa jade lati ẹnu ilẹkun oke wá, ti o wà niha ariwa, olukuluku ton ti ohun-ijà ipani li ọwọ́ rẹ̀: ọkunrin kan ninu wọn si wọ aṣọ ọgbọ̀, pẹlu ìwo-tàdawa akọwe li ẹgbẹ́ rẹ̀: nwọn si wọ inu ile, nwọn si duro lẹba pẹpẹ idẹ.


Nigbana ni emi Danieli wò, si kiyesi i, awọn meji miran si duro: ọ̀kan lapa ihín eti odò, ati ekeji lapa ọhún eti odò.


Emi si gbọ́, ṣugbọn kò ye mi: nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini yio ṣe ikẹhin wọnyi?


Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?


Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.


Bi o si ti joko lori òke Olifi, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá nikọ̀kọ, wipe, Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? Kini yio si ṣe àmi wíwa rẹ, ati ti opin aiye?


Sọ fun wa, nigbawo ni nkan wọnyi yio ṣẹ? kini yio si ṣe àmi nigbati gbogbo nkan wọnyi yio ṣẹ?


Ki a ba le fi ọ̀pọlọpọ onirũru ọgbọ́n Ọlọrun hàn nisisiyi fun awọn ijoye ati awọn alagbara ninu awọn ọrun, nipasẹ ijọ,


Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.


Awọn angẹli meje na si ti inu tẹmpili jade wá, nwọn ni iyọnu meje nì, a wọ̀ wọn li aṣọ ọgbọ funfun ti ndan, a si fi àmure wura dì wọn li õkan àiya.


Awọn ogun ti mbẹ li ọrun ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, funfun ati mimọ́, si ntọ ọ lẹhin lori ẹṣin funfun.


Nwọn kigbe li ohùn rara, wipe, Yio ti pẹ to, Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ati olõtọ, iwọ ki yio ṣe idajọ ki o si gbẹsan ẹ̀jẹ wa mọ́ lara awọn ti ngbé ori ilẹ aiye?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan