Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:4 - Bibeli Mimọ

4 Ṣugbọn iwọ, Danieli sé ọ̀rọ na mọhun, ki o si fi edidi di iwe na, titi fi di igba ikẹhin: ọ̀pọlọpọ ni yio ma wadi rẹ̀, ìmọ yio si di pupọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:4
25 Iomraidhean Croise  

Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.


Iran gbogbo si dabi ọ̀rọ iwe kan fun nyin ti a dí, ti a fi fun ẹnikan ti o mọ̀ ọ kà, wipe, Emi bẹ̀ ọ, kà eyi, ti o si wipe, emi kò le ṣe e; nitori a ti dí i.


Imọ́lẹ oṣupa yio si dabi imọ́lẹ õrun, imọ́lẹ õrun yio si ràn ni iwọ̀n igbà meje, bi imọ́lẹ ọjọ meje, li ọjọ ti Oluwa dí yiya awọn enia rẹ̀, ti o si ṣe àwotán ọgbẹ ti a ṣá wọn.


Oju awọn ẹniti o riran kì yio ṣe baibai, ati eti awọn ti o ngbọ́ yio tẹ́ silẹ.


Di ẹri na, fi edídi di ofin na lãrin awọn ọmọ-ẹhin mi.


Ẹrìn kiri la ita Jerusalemu ja, ki ẹ si wò nisisiyi, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si wakiri nibi gbigbòro rẹ̀, bi ẹ ba lè ri ẹnikan, bi ẹnikan wà ti nṣe idajọ, ti o nwá otitọ; emi o si dari ji i.


LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na.


Njẹ nisisiyi, mo de lati mu ọ moye ohun ti yio ba awọn enia rẹ ni ikẹhin ọjọ: nitori ti ọjọ pipọ ni iran na iṣe.


Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.


Awọn ti o moye ninu awọn enia yio ma kọ́ ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn nwọn o ma ti ipa oju idà ṣubu, ati nipa iná, ati nipa igbekun, ati nipa ikogun nijọmelo kan.


Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.


Ṣugbọn iwọ ma ba ọ̀na rẹ lọ, titi opin yio fi de, iwọ o si simi, iwọ o si dide duro ni ipo rẹ ni ikẹhin ọjọ.


Nigbana ni emi Danieli wò, si kiyesi i, awọn meji miran si duro: ọ̀kan lapa ihín eti odò, ati ekeji lapa ọhún eti odò.


O si wipe, Ma ba ọ̀na rẹ lọ, Danieli, nitoriti a ti se ọ̀rọ na mọ sọhún, a si fi edidi di i titi fi di igba ikẹhin.


Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.


O si wipe, kiyesi i, emi o mu ọ mọ̀ ohun ti yio ṣe ni igba ikẹhin ibinu na: nitoripe, akokò igba ikẹhin ni eyi iṣe.


Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.


A o si wasu ihinrere ijọba yi ni gbogbo aiye lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ède; nigbana li opin yio si de.


Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye.


Nigbati awọn ãrá meje na fọhun, mo mura ati kọwe: mo si gbọ́ ohùn lati ọrun wá nwi fun mi pe, Fi èdidi dí ohun ti awọn ãrá meje na sọ, má si ṣe kọ wọn silẹ.


O si wi fun mi pe, Máṣe fi èdidi di ọ̀rọ isọtẹlẹ ti inu iwe yi: nitori ìgba kù si dẹ̀dẹ̀.


MO si ri li ọwọ́ ọtún ẹniti o joko lori itẹ́ na, iwe kan ti a kọ ninu ati lẹhin, ti a si fi èdidi meje dì.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan