Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:3 - Bibeli Mimọ

3 Awọn ọlọgbọ́n yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọ̀pọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi irawọ̀ lai ati lailai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:3
27 Iomraidhean Croise  

Awọn ọmọ Israeli si ri oju Mose pe, awọ, oju rẹ̀ ndán: Mose si tun fi iboju bò oju rẹ̀, titi o fi wọle lọ bá a sọ̀rọ.


Eso ododo ni igi ìye; ẹniti o ba si yi ọkàn enia pada, ọlọgbọ́n ni.


Awọn ọlọgbọ́n ni yio jogun ogo: ṣugbọn awọn aṣiwere ni yio ru itiju wọn.


Ṣugbọn ipa-ọ̀na awọn olõtọ dabi titàn imọlẹ, ti o ntàn siwaju ati siwaju titi di ọsangangan.


Ati pẹlu, nitori Oniwasu na gbọ́n, o si nkọ́ awọn enia ni ìmọ pẹlu; nitõtọ o ṣe akiyesi daradara, o si wadi, o si fi owe pupọ lelẹ li ẹsẹsẹ.


Yio ri ninu eso lãlã ọkàn rẹ̀, yio si tẹ́ ẹ li ọrùn: nipa imọ̀ rẹ̀ ni iranṣẹ mi olododo yio da ọ̀pọlọpọ lare; nitori yio rù aiṣedede wọn wọnni.


Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.


Awọn ti o moye ninu awọn enia yio ma kọ́ ọ̀pọlọpọ: ṣugbọn nwọn o ma ti ipa oju idà ṣubu, ati nipa iná, ati nipa igbekun, ati nipa ikogun nijọmelo kan.


Awọn ẹlomiran ninu awọn ti o moye yio si ṣubu, lati dan wọn wò, ati lati wẹ̀ wọn mọ́, ati lati sọ wọn di funfun, ani titi fi di akokò opin: nitoripe yio wà li akokò ti a pinnu.


Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i.


Nigbana li awọn olododo yio ma ràn bi õrun ni ijọba Baba wọn. Ẹniti o ba li etí ki o gbọ́.


Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, pe ẹnyin ti ẹ ntọ̀ mi lẹhin, ni igba atunbi, nigbati Ọmọ-enia yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀, ẹnyin o si joko pẹlu lori itẹ́ mejila, ẹnyin o ma ṣe idajọ awọn ẹ̀ya Israeli mejila.


Tani iṣe olõtọ ati ọlọgbọn ọmọ-ọdọ, ẹniti oluwa rẹ̀ fi ṣe olori ile rẹ̀, lati fi onjẹ wọn fun wọn li akokò?


Ẹniti nkorè ngba owo ọ̀ya, o si nkó eso jọ si ìye ainipẹkun: ki ẹniti o nfunrugbin ati ẹniti nkore le jọ mã yọ̀ pọ̀.


On ni fitila ti o njó, ti o si ntànmọlẹ: ẹnyin si fẹ fun sã kan lati mã yọ̀ ninu imọlẹ rẹ̀.


AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu.


Gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun ti a fifun mi, bi ọlọ́gbọn ọ̀mọ̀lé, mo ti fi ipilẹ sọlẹ, ẹlomiran si nmọ le e. Ṣugbọn ki olukuluku kiyesara bi o ti nmọ le e.


O si ti fi awọn kan funni bi aposteli; ati awọn miran bi woli; ati awọn miran bi efangelisti, ati awọn miran bi oluṣọ-agutan ati olukọni;


Nitori nigbati akokò tó ti o yẹ ki ẹ jẹ olukọ, ẹ tun wà ni ẹniti ẹnikan yio mã kọ́ ni ibẹrẹ ipilẹ awọn ọ̀rọ Ọlọrun; ẹ si di irú awọn ti kò le ṣe aini wàra, ti nwọn kò si fẹ onjẹ lile.


Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi ọgbọ́n ti a fifun u;


Ohun ijinlẹ ti irawọ meje na ti iwọ ri li ọwọ́ ọtún mi, ati ọpá wura fitila meje na. Irawọ meje ni awọn angẹli ìjọ meje na: ati ọpá fitila meje na ti iwọ ri ni awọn ijọ meje.


Bẹ̃ni ki o jẹ ki gbogbo awọn ọtá rẹ ki o ṣegbé OLUWA: ṣugbọn jẹ ki awọn ẹniti o fẹ́ ẹ ki o dabi õrùn nigbati o ba yọ ninu agbara rẹ̀. Ilẹ na si simi li ogoji ọdún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan