Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:2 - Bibeli Mimọ

2 Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:2
19 Iomraidhean Croise  

A o yìn enia gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ̀: ṣugbọn ẹni alayidayida aiya li a o gàn.


Awọn okú rẹ yio yè, okú mi, nwọn o dide. Ẹ ji, ẹ si kọrin, ẹnyin ti ngbe inu ekuru: nitori ìri rẹ ìri ewebẹ̀ ni, ilẹ yio si sọ awọn okú jade.


Nwọn o si jade lọ, nwọn o si wò okú awọn ti o ti ṣọtẹ si mi: nitori kokoro wọn kì yio kú, bẹ̃ni iná wọn kì yio si kú; nwọn o si jẹ ohun irira si gbogbo ẹran-ara.


Ṣugbọn Oluwa mbẹ lọdọ mi bi akọni ẹlẹrù, nitorina awọn ti nṣe inunibini si mi yio ṣubu, nwọn kì yio le bori: oju yio tì wọn gidigidi, nitoripe nwọn kì o ṣe rere: a ki yio gbagbe itiju wọn lailai!


Nitorina sọtẹlẹ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, ẹnyin enia mi, emi o ṣi ibojì nyin, emi o si mu ki ẹ dide kuro ninu ibojì nyin, emi o si mu nyin wá si ilẹ Israeli.


Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi.


Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu ìya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.


Mo si ni ireti sipa ti Ọlọrun, eyi ti awọn tikarawọn pẹlu jẹwọ, pe ajinde okú mbọ̀, ati ti olõtọ, ati ti alaiṣõtọ.


O si kunlẹ, o kigbe li ohùn rara pe, Oluwa, má kà ẹ̀ṣẹ yi si wọn li ọrùn. Nigbati o si wi eyi, o sùn.


Amọ̀koko kò ha li agbara lori amọ̀, ninu ìṣu kanna lati ṣe apakan li ohun elo si ọlá, ati apakan li ohun elo si ailọlá?


Nitori bi awa ba gbagbọ́ pe Jesu ti kú, o si ti jinde, gẹgẹ bẹ̃ni Ọlọrun yio mu awọn ti o sùn pẹlu ninu Jesu wá pẹlu ara rẹ̀.


Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan