Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:11 - Bibeli Mimọ

11 Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:11
14 Iomraidhean Croise  

Njẹ eyi ni iwọ o ma fi rubọ lori pẹpẹ na; ọdọ-agutan meji ọlọdún kan li ojojumọ́ lailai.


Nigbati iwọ ba si pari wọn, tun fi ẹgbẹ́ rẹ ọtún dubulẹ, iwọ o si ru ẹ̀ṣẹ ile Juda li ogoji ọjọ: mo ti yàn ọjọ kan fun ọdun kan fun ọ.


Dán awọn ọmọ-ọdọ rẹ wò, emi bẹ̀ ọ, ni ijọ mẹwa; ki o si jẹ ki nwọn ki o ma fi ẹ̀wa fun wa lati jẹ, ati omi lati mu.


Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ.


On o si ma sọ̀rọ nla si Ọga-ogo, yio si da awọn enia-mimọ́ ti Ọga-ogo lagara, yio si rò lati yi akokò ati ofin pada; a o si fi wọn le e lọwọ titi fi di igba akokò kan, ati awọn akokò, ati idaji akokò.


Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.


On o si fi idi majẹmu kan mulẹ fun ọ̀pọlọpọ niwọn ọ̀sẹ kan: ati lãrin ọ̀sẹ na ni yio mu ki a dẹkun ẹbọ, ati ọrẹ-ẹbọ, irira isọdahoro yio si duro lori ibi-mimọ́ titi idajọ ti a pinnu yio túdà sori asọnidahoro.


Nitori ọjọ pupọ̀ li awọn ọmọ Israeli yio gbe li aini ọba, ati li aini olori, ati li aini ẹbọ, li aini ere, ati li aini awòaiyà, ati li aini tẹrafimu.


Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:)


Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:


Si fi agbala ti mbẹ lode tẹmpili silẹ, má si ṣe wọ̀n ọ; nitoriti a fi i fun awọn Keferi: ilu mimọ́ na li nwọn o si tẹ̀ mọlẹ li oṣu mejilelogoji.


Obinrin na si sá lọ si aginjù, nibiti a gbé ti pèse àye silẹ dè e lati ọwọ́ Ọlọrun wá, pe ki nwọn ki o mã bọ́ ọ nibẹ̀ li ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta.


A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan