Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 12:1 - Bibeli Mimọ

1 LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 “Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 12:1
48 Iomraidhean Croise  

Iwọ nka ìrìnkiri mi: fi omije mi sinu igo rẹ: nwọn ko ha si ninu iwe rẹ bi?


Nù wọn kuro ninu iwe awọn alãye, ki a má si kọwe wọn pẹlu awọn olododo.


Yio si ṣe, pe, ẹniti a fi silẹ ni Sioni, ati ẹniti o kù ni Jerusalemu, li a o pè ni mimọ́, ani orukọ olukuluku ẹniti a kọ pẹlu awọn alãye ni Jerusalemu.


Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.


Njẹ nisisiyi, má bẹ̀ru, iwọ Jakobu, ọmọ-ọdọ mi, li Oluwa wi; ki o má si fòya, iwọ Israeli: nitorina sa wò o, emi o gbà ọ lati okere wá, ati iru-ọmọ rẹ lati igbekun wọn; Jakobu yio si pada, yio si wà ni isimi, yio si gbe jẹ, ẹnikan kì yio si dẹruba a.


Oṣe! nitori ọjọ na tobi, tobẹ̃ ti kò si ọkan bi iru rẹ̀: o jẹ àkoko wahala fun Jakobu; sibẹ a o gbà a kuro ninu rẹ̀.


Ọwọ́ mi yio si wà lori awọn woli, ti nwọn ri asan, ti nwọn si nfọ àfọṣẹ eke; nwọn kì yio si ninu ijọ awọn enia mi, bẹ̃ni a kì yio kọwe wọn sinu iwe ile Israeli; bẹ̃ni nwọn kì yio wọ̀ ilẹ Israeli, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.


Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ.


Emi o si ṣe ninu rẹ ohun ti emi kò ṣe ri, iru eyi ti emi kì yio si ṣe mọ, nitori gbogbo ohun irira rẹ.


Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia.


Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.


On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.


Iṣàn iná nṣẹyọ, o si ntu jade lati iwaju rẹ̀ wá; awọn ẹgbẹ̃gbẹrun nṣe iranṣẹ fun u, ati awọn ẹgbẹgbarun nigba ẹgbarun duro niwaju rẹ̀: awọn onidajọ joko, a si ṣi iwe wọnni silẹ.


On si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, eyi ti o sọ si wa, ati si awọn onidajọ wa ti o nṣe idajọ fun wa, nipa eyi ti o fi mu ibi nla bá wa: iru eyi ti a kò ti iṣe si gbogbo abẹ ọrun, gẹgẹ bi a ti ṣe sori Jerusalemu.


Ọjọ òkunkun ati òkudu, ọjọ ikũku ati òkunkun biribiri, bi ọyẹ̀ owurọ̀ ti ilà bò ori awọn oke-nla: enia nla ati alagbara; kò ti isi iru rẹ̀ ri, bẹ̃ni iru rẹ̀ kì yio si mọ lẹhin rẹ̀, titi de ọdun iran de iran.


Nigbana li awọn ti o bẹ̀ru Oluwa mba ara wọn sọ̀rọ nigbakugba; Oluwa si tẹti si i, o si gbọ́, a si kọ iwe-iranti kan niwaju rẹ̀, fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ti nwọn si nṣe aṣaro orukọ rẹ̀.


Nitori nigbana ni ipọnju nla yio wà, irú eyi ti kò si lati igba ibẹrẹ ọjọ ìwa di isisiyi, bẹ̃kọ, irú rẹ̀ kì yio si si.


Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si.


Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.


Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú?


Bẹ̃li a o si gbà gbogbo Israeli là; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ni Sioni li Olugbala yio ti jade wá, yio si yi aiwa-bi-Ọlọrun kuro lọdọ Jakọbu:


Ga ju gbogbo ijọba ati ọla, ati agbara, ati oyè, ati gbogbo orukọ ti a ndá, ki iṣe li aiye yi nikan, ṣugbọn li eyiti mbọ̀ pẹlu.


Mo si bẹ ọ pẹlu, bi alajọru-ajaga mi tõtọ, ran awọn obinrin wọnni lọwọ, nitori nwọn mba mi ṣiṣẹ pọ̀ ninu ihinrere, ati Klementi pẹlu, ati awọn olubaṣiṣẹ mi iyoku pẹlu, orukọ awọn ti mbẹ ninu iwe ìye.


Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.


Ati lati ọdọ Jesu Kristi, ẹlẹri olõtọ, akọbi ninu awọn okú, ati alaṣẹ awọn ọba aiye. Ẹniti o fẹ wa, ti o si wẹ̀ wa ninu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro ninu ẹ̀ṣẹ wa,


Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀.


Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye.


Awọn wọnyi ni yio si mã ba Ọdọ-Agutan jagun, Ọdọ-Agutan na yio si ṣẹgun wọn: nitori on ni Oluwa awọn oluwa, ati Ọba awọn ọba: awọn ti o si wà pẹlu rẹ̀, ti a pè, ti a yàn, ti nwọn si jẹ olõtọ yio si ṣẹgun pẹlu.


Mo si ri awọn okú, ati ewe ati àgba, nwọn duro niwaju itẹ; a si ṣi awọn iwe silẹ; a si ṣí awọn iwe miran kan silẹ ti iṣe iwe ìye: a si ṣe idajọ fun awọn okú lati inu ohun ti a ti kọ sinu awọn iwe na, gẹgẹ bi iṣẹ wọn.


Bi a ba si ri ẹnikẹni ti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe ìye, a sọ ọ sinu adagun iná.


Ẹniti o ba ṣẹgun, on na li a o fi aṣọ funfun wọ̀; emi kì yio pa orukọ rẹ̀ rẹ́ kuro ninu iwe ìye, ṣugbọn emi o jẹwọ orukọ rẹ̀ niwaju Baba mi, ati niwaju awọn angẹli rẹ̀.


Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan