Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:6 - Bibeli Mimọ

6 Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Lẹ́yìn ọdún púpọ̀ wọn yóò dá májẹ̀mú àlàáfíà, ọmọbìnrin ọba gúúsù yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ọba àríwá láti bá a dá májẹ̀mú àlàáfíà, ṣùgbọ́n òun kì yóò lè di agbára apá a rẹ̀ mú, bẹ́ẹ̀ ni òun kì yóò lè dádúró, ṣùgbọ́n a ó tẹrí i rẹ̀ ba àti àwọn tí ó mú un wá, àti ọmọ tí ó bí, àti ẹni tí ó ń mu lọ́kàn le ní gbogbo àkókò wọ̀nyí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:6
9 Iomraidhean Croise  

A si fa imọlẹ wọn sẹhin kuro lọdọ enia buburu, apa giga li o si ṣẹ́.


Ọ̀na rẹ̀ nlọ siwaju nigbagbogbo; idajọ rẹ jina rere kuro li oju rẹ̀; gbogbo awọn ọta rẹ̀ li o nfẹ̀ si.


Ọmọ enia, emi ti ṣẹ apá Farao ọba Egipti; si kiyesi i, a kì yio dì i ki o ba le san, bẹ̃ni a kì yio fi igi si i lati dì i ki o ba lagbara lati di idà mu.


Nitoripe ọba ariwa yio si yipada, yio si kó ọ̀pọlọpọ enia jọ ti yio pọ̀ jù ti iṣaju lọ, yio si wá lẹhin ọdun melokan pẹlu ogun nla, ati ọ̀pọlọpọ ọrọ̀.


Bẹ̃li ọba ariwa yio si wá, yio si mọdi, yio si gbà ilu olodi; apá ogun ọba gusu kì yio le duro, ati awọn ayanfẹ enia rẹ̀, bẹ̃ni kì yio si agbara lati da a duro.


Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.


Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.


Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan