Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:44 - Bibeli Mimọ

44 Ṣugbọn ìhin lati ila-õrùn, ati lati iwọ-õrùn wá yio dãmu rẹ̀: nitorina ni yio ṣe fi ìbinu nla jade lọ lati ma parun, ati lati mu ọ̀pọlọpọ kuro patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

44 Ṣugbọn ìròyìn kan yóo dé láti ìlà oòrùn ati àríwá tí yóo bà á lẹ́rù, yóo sì fi ibinu jáde lọ kọlu ọpọlọpọ, yóo sì pa wọ́n run.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 Ṣùgbọ́n ìròyìn láti ìlà-oòrùn àti láti ìwọ̀-oòrùn yóò mú ìdáríjì bá a, yóò sì fi ìbínú ńlá jáde lọ láti parun, àti láti pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ run pátápátá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:44
8 Iomraidhean Croise  

Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.


Nitoripe ọkọ̀ awọn ara Kittimu yio tọ̀ ọ wá, nitorina ni yio ṣe dãmu, yio si yipada, yio si ni ibinu si majẹmu mimọ́ nì; bẹ̃ni yio ṣe; ani on o yipada, yio si tun ni idapọ pẹlu awọn ti o kọ̀ majẹmu mimọ́ na silẹ.


Ṣugbọn on o lagbara lori iṣura wura, ati ti fadaka, ati lori gbogbo ohun daradara ni ilẹ Egipti: ati awọn ara Libia, awọn ara Etiopia yio si wà lẹhin rẹ̀.


On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.


Ẹkẹfa si tú ìgo tirẹ̀ sori odò nla Eufrate; omi rẹ̀ si gbẹ, ki a le pese ọna fun awọn ọba ati ìla-õrùn wá.


Awọn wọnyi ni inu kan, nwọn o si fi agbara ati ọla wọn fun ẹranko na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan