Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:41 - Bibeli Mimọ

41 Yio si wọ̀ ilẹ ologo nì pẹlu, ọ̀pọlọpọ li a o si bì ṣubu: ṣugbọn awọn wọnyi ni yio si bọ lọwọ rẹ̀, ani Edomu, ati Moabu, ati olori awọn ọmọ Ammoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

41 Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

41 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì tún gbógun ti ilẹ̀ ológo náà pẹ̀lú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè yóò ṣubú, ṣùgbọ́n Edomu, Moabu àti àwọn olórí Ammoni yóò bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:41
9 Iomraidhean Croise  

Sibẹ emi o tun mu igbekun Moabu pada li ọjọ ikẹhin, li Oluwa wi. Titi de ihin ni idajọ Moabu.


Ati nikẹhin emi o tun mu igbekun awọn ọmọ Ammoni pada, li Oluwa wi.


Egipti ati Juda ati Edomu, ati awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, pẹlu gbogbo awọn ti ndá òṣu, ti ngbe aginju: nitori alaikọla ni gbogbo orilẹ-ède yi, ṣugbọn gbogbo ile Israeli jẹ alaikọla ọkàn.


Ṣugbọn ẹniti o tọ̀ ọ wá yio mã ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu ara rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio duro niwaju rẹ̀; on o si duro ni ilẹ daradara nì, ti yio si fi ọwọ rẹ̀ parun.


On o si nà ọwọ rẹ̀ jade si ilẹ wọnni pẹlu, ilẹ Egipti kì yio si là a.


On o si pagọ ãfin rẹ̀ lãrin omi kọju si òke mimọ́ ologo nì; ṣugbọn on o si de opin rẹ̀, kì yio si si ẹniti yio ràn a lọwọ.


Ati lati inu ọkan ninu wọn ni iwo kekere kan ti jade, ti o si di alagbara gidigidi, si iha gusu, ati si iha ila-õrùn, ati si iha ilẹ ogo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan