Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:4 - Bibeli Mimọ

4 Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Lẹ́yìn ìgbà tí ó bá fi ara hàn tán, ìjọba rẹ̀ yóò fọ́, yóò sì pín sí mẹ́rin ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, ìjọba náà kò sì ṣọ́wọ́ àwọn ìran rẹ̀ tàbí kí ó ní agbára tí ó ń lò tẹ́lẹ̀, nítorí, a ó fa ìjọba rẹ̀ tu a ó sì fi fún àwọn mìíràn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:4
24 Iomraidhean Croise  

Nitotọ li àworan asan li enia gbogbo nrìn: nitotọ ni nwọn nyọ ara wọn lẹnu li asan: o nkó ọrọ̀ jọ, kò si mọ̀ ẹniti yio kó wọn lọ.


Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi.


Yio si ṣe, nigba ti emi o ti fà wọn tu kuro tan, emi o pada, emi o si ni iyọ́nu si wọn, emi o si tun mu wọn wá, olukuluku wọn, si ogún rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀.


Ṣugbọn bi nwọn kì o gbọ́, emi o fà orilẹ-ède na tu patapata; emi o si pa wọn run, li Oluwa wi.


Lojukanna ti emi sọ̀rọ si orilẹ-ède kan ati si ijọba kan lati fà a tu, ati lati fà a lulẹ, ati lati pa a run.


Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.


Bayi ni ki iwọ sọ fun u, Oluwa wi bayi; pe, Wò o, eyi ti emi ti kọ́, li emi o wo lulẹ, ati eyi ti emi ti gbìn li emi o fà tu, ani gbogbo ilẹ yi.


Ati sori Elamu ni emi o mu afẹfẹ mẹrin lati igun mẹrẹrin ọrun wá, emi o si tú wọn ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ wọnni, kì o si sí orilẹ-ède kan, nibiti awọn ãsá Elamu kì yio de.


Nigbana li o sọ fun mi, pe, ọmọ enia, Sọtẹlẹ si ẽmi, sọtẹlẹ, si wi fun ẽmi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Iwọ ẽmi, wá lati igun mẹrẹrin, si mí si okú wọnyi, ki nwọn ba le yè.


Danieli dahùn, o si wipe, Mo ri ni iran mi li oru, si kiyesi i, afẹfẹ mẹrẹrin ọrun njà loju okun nla.


Lẹhin eyi, mo ri, si kiyesi i, ẹranko miran, gẹgẹ bi ẹkùn, ti o ni iyẹ-apa ẹiyẹ mẹrin li ẹhin rẹ̀; ẹranko na ni ori mẹrin pẹlu; a si fi agbara ijọba fun u.


Mo si kiyesi awọn iwo na, si wò o, iwo kekere miran kan si jade larin wọn, niwaju eyiti a fa mẹta tu ninu awọn iwo iṣaju: si kiyesi i, oju gẹgẹ bi oju enia wà lara iwo yi, ati ẹnu ti nsọ ohun nlanlà.


Njẹ bi eyini si ti ṣẹ́, ti iwo mẹrin miran si dide duro nipò rẹ̀, ijọba mẹrin ni yio dide ninu orilẹ-ède na, ṣugbọn kì yio ṣe ninu agbara rẹ̀.


Nigbana ni obukọ na nṣe ohun nla pupọpupọ, nigbati o si di alagbara tan, iwo nla na ṣẹ́; ati nipò rẹ̀ iwo mẹrin miran ti iṣe afiyesi si yọ jade si ọ̀na afẹfẹ mẹrẹrin ọrun.


Ã! ã! sá kuro ni ilẹ ariwa, ni Oluwa wi; nitoripe bi afẹfẹ mẹrin ọrun ni mo tu nyin kakiri, ni Oluwa wi.


Angeli na si dahùn o si wi fun mi pe, Wọnyi ni awọn ẹmi mẹrin ti ọrun, ti njade lọ kuro ni iduro niwaju Oluwa gbogbo aiye.


Jesu si mọ̀ ìronu wọn, o si wi fun wọn pe, Ijọba ki ijọba ti o ba yapa si ara rẹ̀, a sọ ọ di ahoro; ilukilu tabi ilekile ti o ba yapa si ara rẹ̀ kì yio duro.


Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ?


LẸHIN eyi ni mo ri angẹli mẹrin duro ni igun mẹrẹrin aiye, nwọn di afẹfẹ mẹrẹrin aiye mu, ki o máṣe fẹ́ sori ilẹ, tabi sori okun, tabi sara igikigi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan