Daniẹli 11:21 - Bibeli Mimọ21 Ni ipò rẹ̀ li enia lasan kan yio dide, ẹniti nwọn kì yio fi ọlá ọba fun: ṣugbọn yio wá lojiji, yio si fi arekereke gbà ijọba. Faic an caibideilYoruba Bible21 Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní21 “Ẹni tí kò níláárí kan yóò rọ́pò rẹ̀, ẹni tí a kò tí ì fi ọlá ọba fún rí. Yóò sì gbógun sí ìjọba nígbà tí ọkàn àwọn ènìyàn balẹ̀ láìbẹ̀rù, yóò sì gbà á pẹ̀lú àrékérekè. Faic an caibideil |