Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:2 - Bibeli Mimọ

2 Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.” Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Ní ìsinsin yìí, mo sọ òtítọ́ fún ọ ọba mẹ́ta yóò dìde sí i ní Persia, àti ẹ̀kẹrin tí yóò jẹ́ ọlọ́rọ̀ ju gbogbo wọn lọ. Tí ó bá ti di alágbára nípa ọrọ̀ rẹ̀, yóò sì ru gbogbo wọn sókè lòdì sí ìjọba Giriki.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:2
17 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni iṣẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu, duro. Bẹ̃li o duro titi di ọdun keji Dariusi, ọba Persia.


Ati li ọjọ Artasasta ni Biṣlami, Mitredati, Tabeeli ati awọn ẹgbẹ rẹ̀ iyokù kọwe si Artasasta, ọba Persia: a si kọ iwe na li ède Siria, a si ṣe itumọ rẹ̀ li ède Siria.


O si ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba lati India, ani titi o fi de Etiopia, lori ẹtadiladoje ìgberiko:)


Ki emi ki o le mu ọ mọ̀ idaju ọ̀rọ otitọ; ki iwọ ki o le ma fi idahùn otitọ fun awọn ti o rán ọ?


LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na.


Yio si rú agbara ati igboya rẹ̀ soke si ọba gusu ti on ti ogun nla; a o si rú ọba gusu soke si ija pẹlu ogun nlanla ati alagbara pupọ; ṣugbọn on kì yio le duro: nitori nwọn o gba èro tẹlẹ si i.


Sa si kiyesi, ẹranko miran, ekeji, ti o dabi ẹranko beari, o si gbé ara rẹ̀ soke li apakan, o si ni egungun-ìha mẹta lẹnu rẹ̀ larin ehin rẹ̀: nwọn si wi fun u bayi pe, Dide ki o si jẹ ẹran pipọ.


Obukọ onirun nì li ọba Hellene: iwo nla ti o wà lãrin oju rẹ̀ mejeji li ọba ekini.


Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.


Mo si ri àgbo na o nkàn siha iwọ-õrùn, ati si ariwa, ati si gusu; tobẹ ti gbogbo ẹranko kò fi le duro niwaju rẹ̀, bẹ̃ni kò si ẹniti o le gbani lọwọ rẹ̀: ṣugbọn o nṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀, o si nṣe ohun nlanla.


Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀.


Bi o ba pè wọn li ọlọrun, awọn ẹniti a fi ọ̀rọ Ọlọrun fun, a kò si le ba iwe-mimọ́ jẹ,


Ẹniti o joko lori itẹ́ nì si wipe, Kiyesi i, mo sọ ohun gbogbo di ọtún. O si wi fun mi pe, Kọwe rẹ̀: nitori ọ̀rọ wọnyi ododo ati otitọ ni nwọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan