Daniẹli 11:12 - Bibeli Mimọ12 Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi. Faic an caibideilYoruba Bible12 Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Nígbà tí a bá kó ogun náà lọ, ọba gúúsù yóò kún fún agbára, yóò sì pa ẹgbẹgbẹ̀rún ní ìpakúpa síbẹ̀ kì yóò ṣẹ́gun. Faic an caibideil |
Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun.