Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 11:11 - Bibeli Mimọ

11 Ọba gusu yio si fi ibinu ru soke, yio si jade wá ba a jà, ani, ọba ariwa na: on o si kó enia pipọ jọ; ṣugbọn a o fi ọ̀pọlọpọ na le e lọwọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 “Nígbà náà ni ọba gúúsù yóò jáde pẹ̀lú ìbínú, yóò sì bá ọba àríwá jà, ẹni tí yóò kó ọmọ-ogun púpọ̀ jọ, ṣùgbọ́n ọba gúúsù yóò borí i wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 11:11
13 Iomraidhean Croise  

Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.


Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.


Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.


Njẹ nisisiyi, emi fi gbogbo ilẹ yi le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi: ati ẹranko igbẹ ni mo fi fun u pẹlu lati sin i.


Yio si kó ọ̀pọlọpọ na lọ, ọkàn rẹ̀ yio si gbé soke; on o si bì ọ̀pọlọpọ ẹgbãrun enia ṣubu; ṣugbọn a kì yio fi ẹsẹ rẹ̀ mulẹ nipa eyi.


Li akokò opin, ọba gusu yio kàn a, ọba ariwa yio si fi kẹkẹ́, ati ẹlẹṣin, ati ọ̀pọlọpọ ọkọ̀, kọ lu u bi afẹyika-ìji: on o si wọ̀ ilẹ wọnni yio si bò wọn mọlẹ, yio si rekọja.


Ṣugbọn ìhin lati ila-õrùn, ati lati iwọ-õrùn wá yio dãmu rẹ̀: nitorina ni yio ṣe fi ìbinu nla jade lọ lati ma parun, ati lati mu ọ̀pọlọpọ kuro patapata.


Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla.


Ati nibikibi ti ọmọ enia wà, ẹranko igbẹ ati ẹiyẹ oju-ọrun li o si fi le ọ lọwọ, o si ti fi ọ ṣe alakoso lori gbogbo wọn. Iwọ li ori wura yi.


Mo si ri i, o sunmọ ọdọ́-àgbo na, o si fi ikoro ibinu sare si i, o lu àgbo na bolẹ, o si ṣẹ́ iwo rẹ̀ mejeji: kò si si agbara ninu àgbo na, lati duro niwaju rẹ̀, ṣugbọn o lù u bolẹ o si tẹ̀ ẹ mọlẹ: kò si si ẹniti o le gbà àgbo na lọwọ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan