Daniẹli 10:8 - Bibeli Mimọ8 Nitorina emi nikan li o kù, ti mo si ri iran nla yi, kò si kù agbara ninu mi: ẹwà mi si yipada lara mi di ibajẹ, emi kò si lagbara mọ. Faic an caibideilYoruba Bible8 Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Ó sì ku èmi nìkan, tí mo rí ìran ńlá yìí, kò sì ku okun kankan fún mi, ojú u mi sì rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, n kò sì ní agbára mọ́. Faic an caibideil |