Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:7 - Bibeli Mimọ

7 Emi Danieli nikanṣoṣo li o si ri iran na, awọn ọkunrin ti o si wà pẹlu mi kò ri iran na; ṣugbọn ìwariri nlanla dà bò wọn, tobẹ̃ ti nwọn fi sá lọ lati fi ara wọn pamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Èmi Daniẹli, ni ẹnìkan tí ó rí ìran náà, àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú u mi, wọn kò rí i, ṣùgbọ́n ìpayà ńlá dà bò wọ́n, wọ́n sálọ wọ́n sì fi ara pamọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:7
8 Iomraidhean Croise  

O si wipe, Mo gbọ́ ohùn rẹ ninu ọgbà, ẹ̀ru si bà mi, nitori ti mo wà ni ìhoho; mo si fi ara pamọ́.


Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀.


Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?


Ọmọ enia, fi ìgbọnriri jẹ onjẹ rẹ, si fi ìwariri ati ikiyesara mu omi rẹ;


Awọn ti o si wà pẹlu mi ri imọlẹ na nitõtọ, ẹ̀ru si ba wọn; ṣugbọn nwọn kò gbọ́ ohùn ẹniti mba mi sọrọ.


Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan.


Iran na si lẹrù tobẹ̃, ti Mose wipe, ẹ̀ru bà mi gidigidi mo si warìri.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan