Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:3 - Bibeli Mimọ

3 Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:3
11 Iomraidhean Croise  

Mefiboṣeti ọmọ Saulu si sọkalẹ lati wá pade ọba, kò wẹ ẹsẹ rẹ̀, kò si fá irungbọ̀n rẹ̀, bẹ̃ni kò si fọ aṣọ rẹ̀ lati ọjọ ti ọba ti jade titi o fi di ọjọ ti o fi pada li alafia.


Bẹ̃li ẹmi rẹ̀ kọ̀ onjẹ, ati ọkàn rẹ̀ kọ̀ onjẹ didùn.


Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ.


On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.


Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.


Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.


Ẹ ko ikogun fàdakà, ẹ ko ikogun wurà! ati iṣura wọn ailopin na, ati ogo kuro ninu gbogbo ohunelò ti a fẹ́.


Ṣugbọn iwọ, nigbati iwọ ba ngbàwẹ, fi oróro kùn ori rẹ, ki o si bọju rẹ;


Iwọ kò fi oróro pa mi li ori: ṣugbọn on ti fi ororo pa mi li ẹsẹ.


Ṣugbọn emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan