Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:21 - Bibeli Mimọ

21 Ṣugbọn emi o fi eyi ti a kọ sinu iwe otitọ hàn ọ: kò si si ẹniti o ràn mi lọwọ si awọn wọnyi, bikoṣe Mikaeli balogun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

21 Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, èmi yóò sọ ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé òtítọ́ fún ọ. (Kò sí ẹni tí ó kún mi lọ́wọ́ fún nǹkan wọ̀nyí bí kò ṣe Mikaeli, ọmọ-aládé e yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:21
14 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia.


LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe.


Ṣugbọn iwọ, Danieli sé ọ̀rọ na mọhun, ki o si fi edidi di iwe na, titi fi di igba ikẹhin: ọ̀pọlọpọ ni yio ma wadi rẹ̀, ìmọ yio si di pupọ.


Ati iran ti alẹ ati ti owurọ ti a ti sọ, otitọ ni; sibẹ, iwọ sé iran na mọ, nitoripe fun ọjọ pipọ ni.


O mu mi mọ̀, o si mba mi sọ̀rọ wipe, Danieli, mo jade wá nisisiyi lati fi oye fun ọ.


Nitorina ki iwọ ki o mọ̀, ki o si ye ọ, pe lati ijade lọ ọ̀rọ na lati tun Jerusalemu ṣe, ati lati tun u kọ́, titi de igba ọmọ-alade Ẹni-ororo na, yio jẹ ọ̀sẹ meje, ati ọ̀sẹ mejilelọgọta: a o si tun igboro rẹ̀ ṣe, a o mọdi rẹ̀, ṣugbọn ni igba wahala.


Nitori Oluwa Ọlọrun kì o ṣe nkan kan, ṣugbọn o fi ohun ikọ̀kọ rẹ̀ hàn awọn woli iranṣẹ rẹ̀.


Ati eyiyi li ọ̀rọ awọn woli ba ṣe dede; bi a ti kọwe rẹ̀ pe,


Li Oluwa wi, ẹniti o sọ gbogbo nkan wọnyi di mimọ̀ fun Ọlọrun ni iṣẹ rẹ̀ gbogbo, lati igba ọjọ ìwa.


Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.


Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan