Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:2 - Bibeli Mimọ

2 Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:2
13 Iomraidhean Croise  

O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun.


Emi o wi fun Ọlọrun, apata mi pe, Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe mi? ẽṣe ti emi fi nrìn ni ìgbawẹ nitori inilara ọta nì.


Nitori iwọ li Ọlọrun agbara mi: ẽṣe ti iwọ fi ṣa mi tì? ẽṣe ti emi fi nrìn ni igbawẹ nitori inilara ọta nì.


Ẹ ba Jerusalemu yọ̀, ki inu nyin si dùn pẹlu rẹ̀, gbogbo ẹnyin ti o fẹ ẹ; ẹ ba a yọ̀ fun ayọ̀, gbogbo ẹnyin ti ngbãwẹ̀ fun u.


ORI mi iba jẹ omi, ati oju mi iba jẹ orisun omije, ki emi le sọkun lọsan ati loru fun awọn ti a pa ninu ọmọbinrin enia mi!


Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ.


Jesu si wi fun wọn pe, Awọn ọmọ ile iyawo ha le gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn? ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn ó gbãwẹ.


Pe mo ni ibinujẹ pupọ, ati ikãnu igbagbogbo li ọkàn mi.


Ki inu nyin ki o bajẹ, ki ẹ si gbàwẹ, ki ẹ si mã sọkun: ẹ jẹ ki ẹrín nyin ki o di àwẹ, ati ayọ̀ nyin ki o di ikãnu.


Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan