Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:16 - Bibeli Mimọ

16 Si wò o, ẹnikan ti jijọ rẹ̀ dabi ti awọn ọmọ enia fi ọwọ kan ète mi: nigbana ni mo ya ẹnu mi, mo si fọhùn, mo si wi fun ẹniti o duro tì mi pe, oluwa mi, niti iran na, irora mi pada sinu mi, emi kò si lagbara mọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nígbà náà, ni ẹnìkan tí ó rí bí ènìyàn fi ọwọ́ kan ètè mi, mo la ẹnu mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ ọ̀rọ̀, mo sọ fún ẹni tí ó dúró níwájú mi, “Ìrònú sì mú mi, nítorí ìran náà, olúwa mi, n kò sì ní okun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:16
29 Iomraidhean Croise  

Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.


On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán.


Nitoripe ninu ọgbọ́n pupọ ni ibinujẹ pupọ wà, ẹniti o si nsọ ìmọ di pupọ, o nsọ ikãnu di pupọ.


O si fi kàn mi li ẹnu, o si wipe, Kiyesi i, eyi ti kàn etè rẹ, a mu aiṣedede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ rẹ nù.


Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu.


Ati lori ofurufu ti o wà lori wọn, aworan itẹ kan wà, bi irí okuta safire: ati loke aworan itẹ na li aworan kan bi ori enia wà.


Ṣugbọn nigbati mo ba bá ọ sọ̀rọ, emi o ya ẹnu rẹ, iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹniti o gbọ́, jẹ ki o gbọ́; ẹniti o kọ̀, jẹ ki o kọ̀ nitori ọlọ̀tẹ ile ni nwọn.


Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi li àṣalẹ, ki ẹniti o salà na to de; o si ti ṣi ẹnu mi, titi on fi wá sọdọ mi li owurọ; ẹnu mi si ṣi, emi kò si yadi mọ.


Emi si gbọ́, ṣugbọn kò ye mi: nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini yio ṣe ikẹhin wọnyi?


Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.


Ẹmi emi Danieli si rẹwẹsi ninu ara mi, iran ori mi si mu mi dãmu.


Titi de ihinyi li opin ọ̀ran na. Bi o ṣe ti emi Danieli ni, igbero inu mi dãmu mi gidigidi, oju mi si yipada lori mi: ṣugbọn mo pa ọran na mọ́ li ọkàn mi.


O si ṣe ti emi, ani emi Danieli si ti ri iran na, ti mo si nfẹ imọ̀ idi rẹ̀, si kiyesi i, ẹnikan duro niwaju mi, gẹgẹ bi aworan ọkunrin.


Bẹ̃li o si wá sibi ti mo duro: nigbati o si de, ẹ̀ru bà mi, mo si da oju mi bolẹ: ṣugbọn o wi fun mi pe, Kiyesi i, ọmọ enia: nitoripe ti akokò igba ikẹhin ni iran na iṣe.


Njẹ bi o ti mba mi sọ̀rọ, mo dãmu, mo si doju bolẹ: ṣugbọn o fi ọwọ kàn mi, o si gbé mi dide duro si ipò mi.


Arẹ̀ si mu emi Danieli, ara mi si ṣe alaida niwọn ọjọ melokan; lẹhin na, mo dide, mo si nṣe iṣẹ ọba; ẹ̀ru si bà mi, nitori iran na, ṣugbọn kò si ẹni ti o fi ye mi.


Bẹni, bi mo ti nwi lọwọ ninu adura mi, ọkunrin na, Gabrieli ti mo ti ri ni iran mi li atetekọṣe, li a mu lati fò wá kankan, o de ọdọ mi niwọn akokò ẹbọ aṣãlẹ.


Ẹnu rẹ̀ si ṣí lọgan, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si sọ̀rọ, o si nyìn Ọlọrun.


Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju.


Tomasi dahun o si wi fun u pe, Oluwa mi ati Ọlọrun mi!


O si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn bi olori ogun OLUWA ni mo wá si nisisiyi. Joṣua si wolẹ niwaju rẹ̀, o si foribalẹ, o si wi fun pe, Kili oluwa mi ni isọ fun iranṣẹ rẹ̀?


Ati lãrin awọn ọpá fitila na, ẹnikan ti o dabi Ọmọ enia, ti a wọ̀ li aṣọ ti o kanlẹ̀ de ẹsẹ, ti a si fi àmure wura dì li ẹgbẹ.


Nigbana ni Manoa bẹ̀ OLUWA, o si wipe, OLUWA, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki enia Ọlọrun, ti iwọ rán tun tọ̀ wa wá, ki o le kọ́ wa li ohun ti awa o ṣe si ọmọ na ti a o bi.


Gideoni si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ibaṣepe OLUWA wà pẹlu wa, njẹ ẽṣe ti gbogbo eyi fi bá wa? nibo ni gbogbo iṣẹ-iyanu rẹ̀ ti awọn baba wa ti sọ fun wa gbé wà, wipe, OLUWA kò ha mú wa gòke lati Egipti wá? ṣugbọn nisisiyi OLUWA ti kọ̀ wa silẹ, o si ti fi wa lé Midiani lọwọ.


O si wi fun u pe, Yẽ oluwa mi, ọ̀na wo li emi o fi gbà Israeli là? kiyesi i, talakà ni idile mi ni Manasse, emi li o si jẹ́ ẹni ikẹhin ni ile baba mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan