Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 10:13 - Bibeli Mimọ

13 Ṣugbọn balogun ijọba Persia nì dè mi li ọ̀na li ọjọ mọkanlelogun: ṣugbọn, wò o, Mikaeli, ọkan ninu awọn olori balogun wá lati ràn mi lọwọ: emi si di ipò mi mu lọdọ awọn ọba Persia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

13 Angẹli, aláṣẹ ìjọba Pasia dè mí lọ́nà fún ọjọ́ mọkanlelogun; ṣugbọn Mikaeli, ọ̀kan ninu àwọn olórí aláṣẹ, ni ó wá ràn mí lọ́wọ́; nítorí wọ́n dá mi dúró sọ́dọ̀ aláṣẹ ìjọba Pasia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Ṣùgbọ́n ọmọ-aládé ìjọba Persia dá mi dúró fún ọjọ́mọ́kànlélógún. Nígbà náà ni Mikaeli, ọ̀kan lára ìjòyè àwọn ọmọ-aládé, wá láti ràn mi lọ́wọ́, nítorí a dá mi dúró níbẹ̀ pẹ̀lú ọba Persia.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 10:13
11 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni iṣẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu, duro. Bẹ̃li o duro titi di ọdun keji Dariusi, ọba Persia.


LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe.


Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun.


A si ti ṣe nyin ni kikún ninu rẹ̀, ẹniti iṣe ori fun gbogbo ijọba ati agbara:


Nitori awa fẹ lati tọ̀ nyin wá, ani emi Paulu lẹ̃kini ati lẹ̃keji; Satani si dè wa li ọ̀na.


Ẹniti o ti lọ si ọrun, ti o si mbẹ li ọwọ́ ọtún Ọlọrun; awọn angẹli, ati awọn ọlọlá, ati awọn alagbara si ntẹriba fun.


Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.


Ogun si mbẹ li ọrun: Mikaeli ati awọn angẹli rẹ̀ ba dragoni na jàgun; dragoni si jàgun ati awọn angẹli rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan