Daniẹli 10:12 - Bibeli Mimọ12 Nigbana ni o wi fun mi pe, má bẹ̀ru, Danieli: lati ọjọ kini ti iwọ ti fi aiya rẹ si lati moye, ti iwọ si npọ́n ara rẹ loju niwaju Ọlọrun rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ rẹ, emi si wá nitori ọ̀rọ rẹ. Faic an caibideilYoruba Bible12 Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní12 Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà. Faic an caibideil |