Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:7 - Bibeli Mimọ

7 Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:7
13 Iomraidhean Croise  

Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti.


Farao-Neko si fi Eliakimu ọmọ Josiah jẹ ọba ni ipò Josiah baba rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Jehoiakimu, o si mu Jehoahasi kuro; on si wá si Egipti, o si kú nibẹ.


Ọba Babeli si fi Mattaniah arakunrin baba rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀, o si pa orukọ rẹ̀ dà si Sedekiah.


Ọba si ba wọn sọ̀rọ: ninu gbogbo wọn, kò si si ẹniti o dabi Danieli, Hananiah, Miṣaeli ati Asariah: nitorina ni nwọn fi nduro niwaju ọba.


Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;


LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na.


Ọba dahùn o si wi fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari pe, Iwọ le fi alá ti mo la hàn fun mi, ati itumọ rẹ̀ pẹlu?


Danieli si bère lọwọ ọba, o si fi Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego jẹ olori ọ̀ran igberiko Babeli; ṣugbọn Danieli joko li ẹnu-ọ̀na ãfin ọba.


Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi.


Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe,


Niwọnbi ẹmi titayọ ati ìmọ, ati oye itumọ alá, oye ati já alọ́, ati lati ma ṣe itumọ ọ̀rọ ti o diju, gbogbo wọnyi li a ri lara Danieli na, ẹniti ọba fi orukọ Belteṣassari fun, njẹ nisisiyi jẹ ki a pè Danieli wá, on o si fi itumọ rẹ̀ hàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan