Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:6
10 Iomraidhean Croise  

Bi awọn ọkunrin mẹta wọnyi, Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, kiki ẹmi ara wọn ni nwọn o fi ododo wọn gbàla, li Oluwa Ọlọrun wi.


Bi Noa, Danieli, ati Jobu tilẹ wà ninu rẹ̀, Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nwọn kì yio gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin là; kìki ọkàn ara wọn ni awọn o fi ododo wọn gbàla.


Wo o, iwọ sa gbọn ju Danieli lọ; kò si si ohun ikọ̀kọ ti o le fi ara sin fun ọ.


Ọba si ba wọn sọ̀rọ: ninu gbogbo wọn, kò si si ẹniti o dabi Danieli, Hananiah, Miṣaeli ati Asariah: nitorina ni nwọn fi nduro niwaju ọba.


Nigbana ni Danieli lọ si ile rẹ̀, o si fi nkan na hàn fun Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀.


Nigbana li Arioku yara mu Danieli lọ siwaju ọba, o si wi bayi fun u pe, Mo ri ọkunrin kan ninu awọn ọmọ igbekun Juda, ẹniti yio fi itumọ na hàn fun ọba.


Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá?


Nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi o si fi ọkàn rẹ̀ si Danieli lati gbà a silẹ: o si ṣe lãlã ati gbà a silẹ titi fi di igbati õrun wọ̀.


Nitorina nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro, ti a ti ẹnu wolĩ Danieli sọ, ti o ba duro ni ibi mimọ́, (ẹniti o ba kà a, ki òye ki o yé e:)


Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke:


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan