Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:4 - Bibeli Mimọ

4 Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:4
23 Iomraidhean Croise  

Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já.


Kò si si arẹwà kan ni gbogbo Israeli ti a ba yìn bi Absalomu: lati atẹlẹsẹ rẹ̀ titi de atari rẹ̀ kò si abùkun kan lara rẹ̀.


Iwọ ri enia ti o nfi aiṣemẹlẹ ṣe iṣẹ rẹ̀? on o duro niwaju awọn ọba; on kì yio duro niwaju awọn enia lasan.


Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu.


Nigbana ni Eliakimu ati Ṣebna ati Joa wi fun Rabṣake pe, Mo bẹ̀ ọ, ba awọn ọmọ-ọdọ rẹ sọ̀rọ li ède Siria, nitori awa gbọ́: má si ṣe ba wa sọ̀rọ li ède Ju, li eti awọn enia ti o wà lori odi.


Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.


Awọn Kaldea si dahùn niwaju ọba, nwọn si wipe, kò si ẹnikan ti o wà li aiye ti o le fi ọ̀ran ọba hàn: kò si si ọba, oluwa, tabi ijoye kan ti o bère iru nkan bẹ̃ lọwọ amoye, tabi ọlọgbọ́n, tabi Kaldea kan ri.


Nigbana ni ọba paṣẹ pe, ki a pè awọn amoye ati ọlọgbọ́n, ati awọn oṣó, ati awọn Kaldea wá, lati fi alá ọba na hàn fun u. Bẹ̃ni nwọn si duro niwaju ọba.


Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn.


Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi.


Ọkunrin kan mbẹ ni ijọba rẹ, lara ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà; ati li ọjọ baba rẹ, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun lara rẹ̀: ẹniti Nebukadnessari ọba, baba rẹ, ani ọba, baba rẹ fi ṣe olori awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ti awọn alafọṣẹ:


Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba.


LI ọdun kini Dariusi, ọmọ Ahasuerusi, lati iru-ọmọ awọn ara Media wá, ti a fi jọba lori ilẹ-ọba awọn ara Kaldea;


O si wi fun u pe, Sare, sọ fun ọdọmọkunrin yi wipe, a o gbe inu Jerusalemu bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọ enia ati ohun-ọsìn inu rẹ̀:


Li akokò na li a bí Mose, ẹniti o li ẹwà pipọ, ti nwọn si bọ́ li oṣù mẹta ni ile baba rẹ̀:


A si kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ará Egipti, o si pọ̀ li ọ̀rọ ati ni iṣe.


Ki on ki o le mu u wá sọdọ ara rẹ̀ bi ìjọ ti o li ogo li aini abawọn, tabi alẽbu kan, tabi irú nkan bawọnni; ṣugbọn ki o le jẹ mimọ́ ati alaini àbuku.


Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan