Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 1:3 - Bibeli Mimọ

3 Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 1:3
6 Iomraidhean Croise  

O si mu Jehoiakini lọ si Babeli, ati iya ọba, ati awọn obinrin ọba, ati awọn iwẹ̀fa rẹ̀, ati awọn alagbara ilẹ na, awọn wọnyi li o kó ni igbèkun lati Jerusalemu lọ si Babeli.


Kiyesi i, ọjọ na dé, ti a o kó ohun gbogbo ti o wà ni ile rẹ, ati ohun ti awọn baba rẹ ti kojọ titi di oni, lọ si Babiloni: kò si nkankan ti yio kù, li Oluwa wi.


Ati ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti yio ti inu rẹ jade, ti iwọ o bi, ni nwọn o kó lọ: nwọn o si jẹ́ iwẹ̀fa ni ãfin ọba Babiloni.


O si ṣe li oṣu keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, ninu iru-ọmọ ọba, ati awọn ijoye ọba, ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, nwọn tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, wá ni Mispa: nibẹ ni nwọn jumọ jẹun ni Mispa.


Iwọ o bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn nwọn ki yio jẹ́ tirẹ; nitoripe nwọn o lọ si oko-ẹrú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan