Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




3 Johanu 1:2 - Bibeli Mimọ

2 Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Olùfẹ́, mo gbadura pé kí ó dára fún ọ ní gbogbo ọ̀nà ati pé kí o ní ìlera, gẹ́gẹ́ bí o ti ní ìlera ninu ẹ̀mí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Olùfẹ́, èmi ń gbàdúrà pé nínú ohun gbogbo kí o lè máa dára fún ọ, kí o sì máa wà ni ìlera, àní bí o tí dára fún ọkàn rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




3 Johanu 1:2
19 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn nigbati Jesu gbọ́, o wi fun wọn pe, Awọn ti ara wọn le kò fẹ oniṣegun, bikoṣe awọn ti ara wọn kò da.


Nitõtọ li o ti ṣe aisan titi de oju ikú: ṣugbọn Ọlọrun ti ṣãnu fun u; kì si iṣe fun on nikan, ṣugbọn fun mi pẹlu, ki emi ki o màṣe ni ibanujẹ lori ibanujẹ.


Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.


Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;


Ṣugbọn iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, olufẹ nipa ti Oluwa, nitori lati àtetekọṣe li Ọlọrun ti yàn nyin si igbala ninu isọdimimọ́ Ẹmí ati igbagbọ́ otitọ:


Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.


Jù gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ni ifẹ ti o gbóna larin ara nyin: nitori ifẹ ni mbò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.


Ṣugbọn ẹ mã dàgba ninu õre-ọfẹ ati ninu ìmọ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi; ẹniti ogo wà fun nisisiyi ati titi lai. Amin.


ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ.


Emi mọ̀ iṣẹ rẹ, ati ipọnju, ati aini rẹ (ṣugbọn ọlọ́rọ̀ ni ọ) emi si mọ̀ ọ̀rọ-òdi si Ọlọrun ti awọn ti nwipe Ju li awọn tikarawọn, ti nwọn kì sì iṣe bẹ̃, ṣugbọn ti nwọn jẹ́ sinagogu ti Satani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan